ILU LILU

Yoruba Educational Series
3 min readJun 13, 2021

--

Ilu, orin ati ijo ti di ohun atirandiran ni ile Yoruba nitori pe lati igba aye awon baba nla wa ni nnkan wonyin ti bere. Gbogbo awon ilu ati abule nlanla to n be nile Yoruba loni awon osere pelu orisirisi ilu ati orin won.

Orisirisi ilu ni o wa fun orisirisi akoko

Ni ile Yoruba, awon kan wa ti won fi ilu se ise se, iran tabi idile yii ni a n pe ni Aayan
Bakan naa won maa n je oruko mo Aayan bi apeere

  • Ayanwale
  • Ayansola
  • Ayanyemi
  • Ayantade
  • Ayansile abbl.

Ona meji la pin ilu si ni ile Yoruba

  1. Awon ilu ti a n lu ni ojo odun ibile
  2. Awon miran tun ni eyi ti a n lu fun orisirisi ayeye.

Awon ilu ti o wa fun orisirisi odun ibile

Awon niwonyi;

  • Bata — Awon onisango ati eleegun ni o saaba maa n jo bats. Owo ilu merin ni a n lu si bata. Awon ni iya ilu, omele abo, omele ako, ati kudu.
  • Ipese — Ilu ti awon babalawo maa n lu ni odun ifa ni Ipese. A tun maa n lu u nibi isinku aso. Merin ni owo ilu Ipese ni. Awon ni: ipese, afere, aran ati agogo.
  • Agere — Ojo odun awon ode ni a maa n lu Agere. Ilu ogun ni. Bakan naa, a maa n lu u nibi oku okan lara awon asaaju ode. Owo ilu meta ni ilu agere ogun. Awon ni: agere, Deere ati afere.
  • Gbedu — Ilu gbede naa ni a tun n pe ni agba iya ilu. Ni ile Yoruba a kii dede lu ilu Gbedu. A maa n fi ilu yi tufo pe Oba waja. A tun maa n fi tufo ijoye pataki ti o teri gbaso. Owo ilu meta ni Gbedu ni.
  • Igbin — Ilu orisa Obatala ni ilu yii, ojo odun Obatala ni awon oloosa yii maa n ko ilu yi sode. Owo ilu merin ni ilu yii ni. Awon ni iya- ilu, iya -gan, kuke ati afere.

Gbogbo awon ilu ti a salaye loke yii ni a ko lo ni ojo lasan, ayafi ojo odun ibile tabi ojo ti ode ba fe lu won.

Ilu ti a n lu fun orisirisi ayeye

Dundun — Ilu ti o le wa gidigidi ni dundun. Mefa ni o parapo ninu ilu yii. Awon ni:

  • iya ilu
  • kerikeri
  • gangan
  • igaanga
  • isaasu
  • kannango
  • ati gudugudu.

Ju gbogbo re lo, a ri i wipe ilu lilu je ohun ti a ko gbodo fowo ro segbe nitori wipe ohun ni o maa n je ki orin wa a dun un jo si.

--

--

Yoruba Educational Series
Yoruba Educational Series

Written by Yoruba Educational Series

YES is an initiative of Onasanya Cecilia that Inspires knowledge and experiences through Pedagogical and Andragogical facilitation of the Yoruba Language.

Responses (1)